Gẹnẹsisi 49:27
Genesis 49:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Benjamini jẹ́ ìkookò tí ó burú; ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran ọdẹ rẹ, ní àṣálẹ́, ó pín ìkógun.”
Genesis 49:27 in English
Genesis 49:27 · Berean Standard Bible
Benjamin is a ravenous wolf; in the morning he devours the prey, in the evening he divides the plunder.”
Context
25nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́,
nítorí Olódùmarè tí ó bùkún ọ
pẹ̀lú láti ọ̀run wá,
ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìsàlẹ̀,
ìbùkún ti ọmú àti ti inú. 26Ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀
ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì,
ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé.
Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Josẹfu,
lé ìpéǹpéjú ọmọ-aládé láàrín arákùnrin rẹ̀. 27“Benjamini jẹ́ ìkookò tí ó burú;
ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran ọdẹ rẹ,
ní àṣálẹ́, ó pín ìkógun.” 28Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i. 29Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́rẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hiti ará Efroni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.