Native Bible

Genesis 49:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára, ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le, nítorí ọwọ́ alágbára Jakọbu, nítorí olùtọ́jú àti aláàbò àpáta Israẹli,

Genesis 49:24 in English

Genesis 49:24 · Berean Standard Bible

Yet he steadied his bow, and his strong arms were tempered by the hands of the Mighty One of Jacob, in the name of the Shepherd, the Rock of Israel,

Context

22“Josẹfu jẹ́ àjàrà eléso, àjàrà eléso ní etí odò, tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi. 23Pẹ̀lú ìkorò, àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́, wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra. 24Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára, ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le, nítorí ọwọ́ alágbára Jakọbu, nítorí olùtọ́jú àti aláàbò àpáta Israẹli, 25nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́, nítorí Olódùmarè tí ó bùkún ọ pẹ̀lú láti ọ̀run wá, ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìsàlẹ̀, ìbùkún ti ọmú àti ti inú. 26Ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀ ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì, ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé. Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Josẹfu, lé ìpéǹpéjú ọmọ-aládé láàrín arákùnrin rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.