Native Bible

Genesis 48:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí, ojú Israẹli ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Josẹfu sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnukò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn.

Genesis 48:10 in English

Genesis 48:10 · Berean Standard Bible

Now Israel’s eyesight was poor because of old age; he could hardly see. Joseph brought his sons to him, and his father kissed them and embraced them.

Context

8Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó béèrè wí pé, “Àwọn wo nìyí?” 9Josẹfu fún baba rẹ̀ lésì pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín.” Nígbà náà ni Israẹli wí pé, “Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó ba à le súre fún wọn.” 10Báyìí, ojú Israẹli ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Josẹfu sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnukò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn. 11Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.” 12Nígbà náà ni Josẹfu kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹríba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.