Gẹnẹsisi 45:22
Genesis 45:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun. Ṣùgbọ́n Benjamini ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹyọ owó idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn-ún.
Genesis 45:22 in English
Genesis 45:22 · Berean Standard Bible
He gave new garments to each of them, but to Benjamin he gave three hundred shekels of silver * and five sets of clothes.
Context
20Ẹ má ṣe àníyàn nípa ohun ìní yín nítorí èyí tí ó dára jù nínú ilẹ̀ Ejibiti yóò jẹ́ tiyín.’ ” 21Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí. Josẹfu fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Farao ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìnàjò wọn pẹ̀lú. 22Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun. Ṣùgbọ́n Benjamini ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹyọ owó idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn-ún. 23Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó ránṣẹ́ sí baba rẹ̀: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru àwọn ohun mèremère ilẹ̀ Ejibiti àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti oríṣìíríṣìí oúnjẹ. 24Nígbà náà ni ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń pínyà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jà ní ọ̀nà o!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.