Gẹnẹsisi 45:19
Genesis 45:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe èyí. ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Ejibiti fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín. Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá.
Genesis 45:19 in English
Genesis 45:19 · Berean Standard Bible
You are also directed to tell them: ‘Take wagons from the land of Egypt for your young children and your wives, and bring your father and come back.
Context
17Farao wí fún Josẹfu pé, “Wí fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ di ẹrù lé ẹranko yín kí ẹ sì padà sí ilẹ̀ Kenaani, 18kí ẹ sì mú baba yín àti ìdílé yín tọ̀ mí wá. Èmi yóò fún un yín ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sì le è gbádùn ilẹ̀ yìí.’ 19“A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe èyí. ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Ejibiti fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín. Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá. 20Ẹ má ṣe àníyàn nípa ohun ìní yín nítorí èyí tí ó dára jù nínú ilẹ̀ Ejibiti yóò jẹ́ tiyín.’ ” 21Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí. Josẹfu fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Farao ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìnàjò wọn pẹ̀lú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.