Gẹnẹsisi 45:14
Genesis 45:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ó dì mọ́ Benjamini arákùnrin rẹ̀, ó sì sọkún, Benjamini náà sì dì mọ́ ọn, pẹ̀lú omijé lójú.
Genesis 45:14 in English
Genesis 45:14 · Berean Standard Bible
Then Joseph threw his arms around his brother Benjamin and wept, and Benjamin wept as they embraced.
Context
12“Ẹ̀yin fúnra yín àti Benjamini arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Josẹfu ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀. 13Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Ejibiti àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá.” 14Nígbà náà ni ó dì mọ́ Benjamini arákùnrin rẹ̀, ó sì sọkún, Benjamini náà sì dì mọ́ ọn, pẹ̀lú omijé lójú. 15Ó sì tún fẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì sọkún sí wọn lára. Lẹ́yìn èyí, Josẹfu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀. 16Nígbà tí ìròyìn náà dé ààfin Farao pé àwọn arákùnrin Josẹfu dé, inú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ dùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.