Native Bible

Genesis 45:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò gbé ní agbègbè Goṣeni, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní.

Genesis 45:10 in English

Genesis 45:10 · Berean Standard Bible

You shall settle in the land of Goshen and be near me—you and your children and grandchildren, your flocks and herds, and everything you own.

Context

8“Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi wá sí ibí yìí, bí kò ṣe Ọlọ́run. Ó fi mí ṣe baba, Olùdámọ̀ràn fún Farao, olúwa fún gbogbo ilé Farao àti alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. 9Nísinsin yìí, ẹ yára padà sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ sì wí fun un pé, èyí ni ohun tí Josẹfu ọmọ rẹ wí, Ọlọ́run ti fi mí ṣe olúwa fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, ẹ sọ̀kalẹ̀ wá láì jáfara. 10Ìwọ yóò gbé ní agbègbè Goṣeni, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní. 11Èmi yóò pèsè fún yín níbẹ̀. Nítorí ó ṣì ku ọdún márùn-ún gbáko ti ìyàn yóò fi mú. Kí ìwọ àti ilé rẹ àti ohun tí í ṣe tìrẹ má ba à di aláìní. 12“Ẹ̀yin fúnra yín àti Benjamini arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Josẹfu ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.