Native Bible

Genesis 44:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nítorí náà, bí a bá padà tọ baba wa lọ láìsí ọmọ náà pẹ̀lú wa nígbà tí a mọ̀ pé, ọmọ náà ni ẹ̀mí baba wa.

Genesis 44:30 in English

Genesis 44:30 · Berean Standard Bible

So if the boy is not with us when I return to your servant, and if my father, whose life is wrapped up in the boy’s life,

Context

28Ọ̀kan nínú wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, mo sì wí pé, “Dájúdájú a ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” N kò sì tí ì ri láti ọjọ́ náà. 29Tí ẹ bá tún mú èyí lọ, kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ohunkóhun bá ṣe é, ìbànújẹ́ ni ẹ ó fi mú ewú orí mi lọ sí ipò òkú.’ 30“Nítorí náà, bí a bá padà tọ baba wa lọ láìsí ọmọ náà pẹ̀lú wa nígbà tí a mọ̀ pé, ọmọ náà ni ẹ̀mí baba wa. 31Tí ó bá ri pé ọmọkùnrin náà kò wá pẹ̀lú wa, yóò kùú. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò wá mú baba wa tòun ti ewú orí lọ sí ipò òkú ní ìbànújẹ́. 32Ìránṣẹ́ rẹ ló ṣe onídùúró fún ààbò ọmọ náà lọ́dọ̀ baba mi. Mo wí pé, ‘Bí n kò bá mú un padà tọ̀ ọ́ wá, baba mi, èmi ó ru ẹ̀bi rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi!’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.