Gẹnẹsisi 44:23
Genesis 44:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ìwọ wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ má ṣe padà tọ̀ mí wá àyàfi bí àbíkẹ́yìn yín bá bá yín wá.’
Genesis 44:23 in English
Genesis 44:23 · Berean Standard Bible
But you said to your servants, ‘Unless your younger brother comes down with you, you will not see my face again.’
Context
21“Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ mu un tọ̀ mí wá kí n le fojú ara mi rí i.’ 22A sì sọ fún olúwa à mi pé, ‘Ọmọkùnrin náà kò le è fi baba rẹ̀ sílẹ̀, bí ó bá dán an wò baba rẹ̀ yóò kú.’ 23Ṣùgbọ́n ìwọ wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ má ṣe padà tọ̀ mí wá àyàfi bí àbíkẹ́yìn yín bá bá yín wá.’ 24Nígbà tí a padà lọ sọ́dọ̀ baba wa, tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ, a sọ ohun tí olúwa à mi wí fún un. 25“Nígbà náà ni baba wa wí pé, ‘Ẹ padà lọ láti lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.