Native Bible

Genesis 44:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúkúlùkù wọn yára sọ àpò rẹ̀ kalẹ̀, wọ́n sì tú u.

Genesis 44:11 in English

Genesis 44:11 · Berean Standard Bible

So each one quickly lowered his sack to the ground and opened it.

Context

9Bí a bá rí i lọ́wọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kíkú ni yóò kú, àwọn tí ó kù yóò sì di ẹrú fún olúwa à rẹ.” 10Ó wí pé, “Ó dára, kí ó rí bí ẹ ti ṣe sọ. Ẹnikẹ́ni tí mo bá rí i lọ́wọ́ rẹ̀ yóò di ẹrú mi. Ẹ̀yin tí ó kù yóò sì wà láìlẹ́bi.” 11Olúkúlùkù wọn yára sọ àpò rẹ̀ kalẹ̀, wọ́n sì tú u. 12Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní í wá a, bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹ̀gbọ́n títí lọ sórí àbúrò pátápátá. Ó sì rí kọ́ọ̀bù náà nínú àpò ti Benjamini. 13Nígbà tí wọ́n rí èyí, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì banújẹ́ gidigidi, wọn tún ẹrù wọn dì sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì padà sí inú ìlú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.