Native Bible

Genesis 43:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló ṣèèṣì fi síbẹ̀.

Genesis 43:12 in English

Genesis 43:12 · Berean Standard Bible

Take double the silver with you so that you may return the silver that was put back into the mouths of your sacks. Perhaps it was a mistake.

Context

10Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ìbá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.” 11Nígbà náà ni Israẹli baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà—ìkunra díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjìá, èso pisitakio àti èso almondi 12ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló ṣèèṣì fi síbẹ̀. 13Ẹ mú arákùnrin yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ki ẹ sì tọ arákùnrin náà lọ. 14Kí Ọlọ́run alágbára jẹ́ kí ẹ rí àánú gbà lọ́dọ̀ ọkùnrin náà kí ó ba à le jẹ́ kí arákùnrin yín tí ó wà lọ́hùn ún àti Benjamini padà wá pẹ̀lú yín. Ní tèmi, bí mo bá pàdánù àwọn ọmọ mi, n ó ṣọ̀fọ̀ wọn náà ni.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.