Gẹnẹsisi 43:10
Genesis 43:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ìbá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”
Genesis 43:10 in English
Genesis 43:10 · Berean Standard Bible
If we had not delayed, we could have come and gone twice by now.”
Context
8Juda sì wí fún Israẹli baba rẹ̀, “Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú. 9Èmi fúnra mi yóò ṣe onídùúró fún un, èmi ni kí o gbà pé o fi lé lọ́wọ́. Bí n kò bá sì mú un padà tọ̀ ọ́ wá, jẹ́ kí ẹ̀bi rẹ̀ kí ó jẹ́ tèmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi níwájú rẹ. 10Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ìbá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.” 11Nígbà náà ni Israẹli baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà—ìkunra díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjìá, èso pisitakio àti èso almondi 12ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló ṣèèṣì fi síbẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.