Gẹnẹsisi 42:24
Genesis 42:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni kúrò láàrín wọn, ó sì dè é ní ojú wọn.
Genesis 42:24 in English
Genesis 42:24 · Berean Standard Bible
And he turned away from them and wept. When he turned back and spoke to them, he took Simeon from them and had him bound before their eyes.
Context
22Reubeni dá wọn ní ohùn pé, “Èmi kò wí fún yín pé kí ẹ má se ṣẹ̀ sí ọmọdékùnrin náà? Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa.” 23Wọn kò sì mọ̀ pé, Josẹfu ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀. 24Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni kúrò láàrín wọn, ó sì dè é ní ojú wọn. 25Josẹfu pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padà sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padà sílé. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn, 26wọn gbé ẹrù wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọn sì padà lọ sí ilé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.