Native Bible

Genesis 41:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Farao jí.

Genesis 41:4 in English

Genesis 41:4 · Berean Standard Bible

And the cows that were sickly and thin devoured the seven sleek, well-fed cows. Then Pharaoh woke up,

Context

2Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko. 3Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Naili, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà. 4Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Farao jí. 5Ó sì tún padà sùn, ó sì lá àlá mìíràn: ó rí síírí ọkà méje tí ó kún, ó yómọ, ó sì dára, ó sì jáde lára igi ọkà kan ṣoṣo. 6Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yómọ, afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.