Gẹnẹsisi 41:28
Genesis 41:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bí mo ti wí fún Farao ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Farao.
Genesis 41:28 in English
Genesis 41:28 · Berean Standard Bible
It is just as I said to Pharaoh: God has shown Pharaoh what He is about to do.
Context
26Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, síírí ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni. 27Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni síírí ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ dànù tan, wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú. 28“Bí mo ti wí fún Farao ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Farao. 29Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ̀ yanturu ń bọ̀ wà ní Ejibiti. 30Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú ń bọ̀, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé gbogbo ọ̀pọ̀ ní ilẹ̀ Ejibiti, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.