Native Bible

Genesis 41:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

sì kíyèsi i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀.

Genesis 41:18 in English

Genesis 41:18 · Berean Standard Bible

when seven cows, well-fed and sleek, came up from the river and began to graze among the reeds.

Context

16Josẹfu dá Farao ní ohùn pé, “Kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fi ìdáhùn àlàáfíà fún Farao ní ìtumọ̀ àlá náà.” 17Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Naili, 18sì kíyèsi i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀. 19Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógó, wọn kò sì lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ tí n kò tí ì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Ejibiti. 20Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.