Native Bible

Genesis 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èso ilẹ̀ rẹ̀.

Genesis 4:3 in English

Genesis 4:3 · Berean Standard Bible

So in the course of time, Cain brought some of the fruit of the soil as an offering to the LORD,

Context

1Adamu sì bá aya rẹ̀ Efa lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Kaini. Ó wí pé, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa ni mo bí ọmọ ọkùnrin.” 2Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli. Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀. 3Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èso ilẹ̀ rẹ̀. 4Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀, 5ṣùgbọ́n Olúwa kò fi ojúrere wo Kaini àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí Kaini gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.