Gẹnẹsisi 4:19
Genesis 4:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lameki sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkínní ni Adah, àti orúkọ èkejì ni Silla.
Genesis 4:19 in English
Genesis 4:19 · Berean Standard Bible
And Lamech married two women, one named Adah and the other Zillah.
Context
17Kaini sì bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Enoku. Kaini sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Enoku sọ ìlú náà. 18Enoku sì bí Iradi, Iradi sì ni baba Mehujaeli, Mehujaeli sì bí Metuṣaeli, Metuṣaeli sì ni baba Lameki. 19Lameki sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkínní ni Adah, àti orúkọ èkejì ni Silla. 20Adah sì bí Jabali, òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. 21Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.