Gẹnẹsisi 37:33
Genesis 37:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, “Háà! Aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àní àní, ó ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.”
Genesis 37:33 in English
Genesis 37:33 · Berean Standard Bible
His father recognized it and said, “It is my son’s robe! A vicious animal has devoured him. Joseph has surely been torn to pieces!”
Context
31Nígbà náà ni wọ́n mú aṣọ Josẹfu, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì tẹ aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà. 32Wọ́n sì mú aṣọ ọlọ́nà aláràbarà náà padà sí ọ̀dọ̀ baba wọn, wọ́n sì wí pé, “A rí èyí he nínú oko, yẹ̀ ẹ́ wò, kí o sì mọ̀ bóyá ti ọmọ rẹ ni.” 33Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, “Háà! Aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àní àní, ó ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” 34Nígbà náà ni Jakọbu fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. 35Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, lóbìnrin wá láti tù ú nínú, ṣùgbọ́n kò gbà. Ó wí pé, “Rárá, nínú ọ̀fọ̀ yìí ni èmi yóò lọ sí isà òkú lọ́dọ̀ ọmọ mi.” Baba Josẹfu sì sọkún fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.