Gẹnẹsisi 32:28
Genesis 32:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”
Genesis 32:28 in English
Genesis 32:28 · Berean Standard Bible
Then the man said, “Your name will no longer be Jacob,* but Israel,* because you have struggled with God and with men, and you have prevailed.”
Context
26Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.”
Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.” 27Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀.
Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.” 28Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.” 29Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.”
Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀. 30Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.