Gẹnẹsisi 32:15
Genesis 32:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ọgbọ̀n abo ìbákasẹ pẹ̀lú ọmọ wọn, ogójì abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá.
Genesis 32:15 in English
Genesis 32:15 · Berean Standard Bible
30 milk camels with their young, 40 cows, 10 bulls, 20 female donkeys, and 10 male donkeys.
Context
13Ó sì lo òru ọjọ́ náà níbẹ̀. Ó mú ẹ̀bùn fún Esau arákùnrin rẹ̀ nínú ohun ìní rẹ̀. 14Igba ewúrẹ́, ogún òbúkọ, igba àgùntàn, ogún àgbò, 15ọgbọ̀n abo ìbákasẹ pẹ̀lú ọmọ wọn, ogójì abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá. 16Ó sì fi wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrín ọ̀wọ́ agbo ẹran kọ̀ọ̀kan sí èkejì.” 17Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, “Nígbà tí arákùnrin mi Esau bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.