Gẹnẹsisi 31:45
Genesis 31:45 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jakọbu sì mú òkúta kan ó sì gbé e dúró bí ọ̀wọ́n.
Genesis 31:45 in English
Genesis 31:45 · Berean Standard Bible
So Jacob picked out a stone and set it up as a pillar,
Context
43Labani sì dá Jakọbu lóhùn, “Tèmi ni àwọn obìnrin wọ̀nyí, ọmọ mi ni àwọn ọmọ wọ̀nyí pẹ̀lú, àwọn agbo ẹran yìí, tèmi ni wọ́n pẹ̀lú. Gbogbo ohun tí o rí wọ̀nyí, tèmi ni. Kí ni mo wá le ṣe sí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí àti àwọn ọmọ wọn tí wọn bí? 44Wá, jẹ́ kí a dá májẹ̀mú pẹ̀lú ara wa, èyí yóò sì jẹ́ ẹ̀rí ní àárín wa.” 45Jakọbu sì mú òkúta kan ó sì gbé e dúró bí ọ̀wọ́n. 46Ó sì wí fún àwọn ìbátan rẹ̀ pé, “Ẹ kó àwọn òkúta díẹ̀ jọ.” Wọ́n sì kó òkúta náà jọ bí òkìtì wọ́n sì jẹun níbẹ̀. 47Labani sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jegari-Sahaduta, ṣùgbọ́n Jakọbu pè é ni Galeedi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.