Native Bible

Genesis 31:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kẹta ni Labani gbọ́ pé Jakọbu ti sálọ.

Genesis 31:22 in English

Genesis 31:22 · Berean Standard Bible

On the third day Laban was informed that Jacob had fled.

Context

20Síwájú sí i, Jakọbu tan Labani ará Aramu, nítorí kò sọ fún un wí pé òun ń sálọ. 21Ó sì sálọ pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ni, ó sì la odò kọjá (Eufurate), ó sì kọrí sí àwọn ilẹ̀ olókè ti Gileadi. 22Ní ọjọ́ kẹta ni Labani gbọ́ pé Jakọbu ti sálọ. 23Ó sì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lépa Jakọbu, ó sì lépa wọn fún ọjọ́ méje, ó sì bá wọn ní òkè Gileadi. 24Ọlọ́run sì yọ sí Labani ará Aramu lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.