Gẹnẹsisi 3:9
Genesis 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?”
Genesis 3:9 in English
Genesis 3:9 · Berean Standard Bible
But the LORD God called out to the man, “Where are you?”
Context
7Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn. 8Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà, nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárín àwọn igi inú ọgbà. 9Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?” 10Ó dáhùn pé, “Mo gbúròó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí, nítorí pé, mo wà ní ìhòhò, mo sì fi ara pamọ́.” 11Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.