Gẹnẹsisi 27:38
Genesis 27:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Esau sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi? Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau sì sọkún kíkankíkan.
Genesis 27:38 in English
Genesis 27:38 · Berean Standard Bible
Esau said to his father, “Do you have only one blessing, my father? Bless me too, O my father!” Then Esau wept aloud.
Context
36Esau sì wí pé, “Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jakọbu* bí? Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ: ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsin yìí, ó tún gba ìbùkún mi!” O sì béèrè pé, “Ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni?” 37Isaaki sì dá Esau lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún un, àti ọkà àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?” 38Esau sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi? Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau sì sọkún kíkankíkan. 39Isaaki baba rẹ̀ sì dá a lóhùn pé,
“Ibùjókòó rẹ
yóò jìnnà sí ọ̀rá ilẹ̀,
àti sí ibi ìrì ọ̀run láti òkè wá. 40Nípa idà rẹ ni ìwọ yóò máa gbé,
ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ,
ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbára
ìwọ yóò já àjàgà rẹ̀
kúrò lọ́rùn rẹ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.