Native Bible

Genesis 27:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

bí baba mi bá fọwọ́ kàn mi ń kọ́? Èmi yóò jọ ẹlẹ́tàn lójú rẹ̀, dípò kí ó súre fún mi, èmi yóò sì mú ègún wá sórí ara mi.”

Genesis 27:12 in English

Genesis 27:12 · Berean Standard Bible

What if my father touches me? Then I would be revealed to him as a deceiver, and I would bring upon myself a curse rather than a blessing.”

Context

10Ìwọ yóò sì gbé e tọ baba rẹ lọ, kí òun ba à lè jẹ ẹ́, kí ó sì súre fún ọ, kí ó tó kú.” 11Jakọbu sì wí fún Rebeka ìyá rẹ̀ pé, “Ṣùgbọ́n Esau ẹ̀gbọ́n mi jẹ́ ènìyàn onírun lára, bẹ́ẹ̀ alára ọ̀bọ̀rọ́ sì ni èmi, 12bí baba mi bá fọwọ́ kàn mi ń kọ́? Èmi yóò jọ ẹlẹ́tàn lójú rẹ̀, dípò kí ó súre fún mi, èmi yóò sì mú ègún wá sórí ara mi.” 13Ìyá rẹ̀ wá wí fun un pé, “Ọmọ mi jẹ́ kí ègún náà wá sórí mi, sá à ṣe ohun tí mo wí, kí o sì mú wọn wá fún mi.” 14Jakọbu sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rebeka sì ṣe oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Isaaki fẹ́ràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.