Gẹnẹsisi 24:62
Genesis 24:62 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Isaaki sì ń ti ọ̀nà kànga Lahai-Roi bọ, nítorí ìhà gúúsù ni ó ń gbé.
Genesis 24:62 in English
Genesis 24:62 · Berean Standard Bible
Now Isaac had just returned from Beer-lahai-roi, for he was living in the Negev.
Context
60Wọ́n sì súre fún Rebeka, wọn sì wí fun un pé,
“Ìwọ ni arábìnrin wa
ìwọ yóò di ìyá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;
ǹjẹ́ kí àwọn irú-ọmọ rẹ
kí ó ni ẹnu ibodè ọ̀tá wọn.” 61Nígbà náà ni Rebeka àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ múra, wọn sì gun àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì bá ọkùnrin náà padà lọ. Ìránṣẹ́ náà sì mú Rebeka, ó sì bá tirẹ̀ lọ. 62Isaaki sì ń ti ọ̀nà kànga Lahai-Roi bọ, nítorí ìhà gúúsù ni ó ń gbé. 63Isaaki sì jáde lọ sí oko ni ìrọ̀lẹ́ láti ṣe àṣàrò, bí ó sì ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ìbákasẹ tí ń bọ̀ wá. 64Rebeka pẹ̀lú sì gbójú sókè, ó sì rí Isaaki. Ó sọ̀kalẹ̀ lórí ìbákasẹ,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.