Gẹnẹsisi 23:7
Genesis 23:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Abrahamu dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà, àwọn ará Hiti.
Genesis 23:7 in English
Genesis 23:7 · Berean Standard Bible
Then Abraham rose and bowed down before the people of the land, the Hittites.
Context
5Àwọn ọmọ Hiti dá Abrahamu lóhùn pé, 6“Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrín wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dára jù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dù ọ́ láti sin òkú rẹ sí.” 7Nígbà náà ni Abrahamu dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà, àwọn ará Hiti. 8Ó sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá ṣe pé, lóòótọ́ ni ẹ fẹ́ kí n sin òkú mi kúrò nílẹ̀, ẹ gbọ́ tèmi, ẹ bá mi bẹ Efroni ọmọ Sohari, 9kí ó ta ihò àpáta Makpela tí ó jẹ́ tirẹ̀ fún mi, èyí tí ó wà ni orí oko rẹ̀, kí ó tà á fún mi ni iye owó tí à ń ta irú rẹ̀ fún ilẹ̀ ìsìnkú láàrín yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.