Gẹnẹsisi 22:10
Genesis 22:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀.
Genesis 22:10 in English
Genesis 22:10 · Berean Standard Bible
Then Abraham reached out his hand and took the knife to slaughter his son.
Context
8Abrahamu sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì jùmọ̀ ń lọ. 9Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Abrahamu, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igi lé e lórí, ó sì di Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà. 10Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀. 11Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!”
Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” 12Angẹli Olúwa sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.