Gẹnẹsisi 21:8
Genesis 21:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Isaaki lẹ́nu ọmú, Abrahamu ṣe àsè ńlá.
Genesis 21:8 in English
Genesis 21:8 · Berean Standard Bible
So the child grew and was weaned, and Abraham held a great feast on the day Isaac was weaned.
Context
6Sara sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.” 7Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Abrahamu pé, Sara yóò di ọlọ́mọ? Síbẹ̀síbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Abrahamu ní ìgbà ogbó rẹ.” 8Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Isaaki lẹ́nu ọmú, Abrahamu ṣe àsè ńlá. 9Ṣùgbọ́n Sara rí ọmọ Hagari ará Ejibiti tí ó bí fún Abrahamu tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà, 10ó sì wí fún Abrahamu pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Isaaki pín ogún.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.