Gẹnẹsisi 21:26
Genesis 21:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Abimeleki dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí. Ìwọ kò sì sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbọ́, bí kò ṣe lónìí.”
Genesis 21:26 in English
Genesis 21:26 · Berean Standard Bible
Abimelech replied, “I do not know who has done this. You did not tell me, so I have not heard about it until today.”
Context
24Abrahamu sì wí pé, “Èmí búra.” 25Nígbà náà ni Abrahamu fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Abimeleki nípa kànga tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀. 26Ṣùgbọ́n Abimeleki dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí. Ìwọ kò sì sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbọ́, bí kò ṣe lónìí.” 27Abrahamu sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Abimeleki. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú. 28Abrahamu sì ya abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.