Native Bible

Genesis 20:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Abrahamu sì sọ ní ti Sara aya rẹ̀ níbẹ̀ pé, “Arábìnrin mi ni.” Abimeleki ọba Gerari sì ránṣẹ́ mú Sara wá sí ààfin rẹ̀.

Genesis 20:2 in English

Genesis 20:2 · Berean Standard Bible

Abraham said of his wife Sarah, “She is my sister.” So Abimelech king of Gerar had Sarah brought to him.

Context

1Abrahamu sì kó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìhà gúúsù ó sì ń gbé ní agbede-méjì Kadeṣi àti Ṣuri; ó sì gbé ní ìlú Gerari fún ìgbà díẹ̀. 2Abrahamu sì sọ ní ti Sara aya rẹ̀ níbẹ̀ pé, “Arábìnrin mi ni.” Abimeleki ọba Gerari sì ránṣẹ́ mú Sara wá sí ààfin rẹ̀. 3Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tọ Abimeleki wá ní ojú àlá lọ́jọ́ kan, ó sì wí fún un pé, “Kíyèsi, kò sí ohun tí o fi sàn ju òkú lọ, nítorí obìnrin tí ìwọ mú sọ́dọ̀ n nì, aya ẹni kan ní íṣe.” 4Ṣùgbọ́n Abimeleki kò tí ìbá obìnrin náà lòpọ̀, nítorí náà ó wí pé, “Olúwa ìwọ yóò run orílẹ̀-èdè aláìlẹ́bi bí?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.