Gẹnẹsisi 16:7
Genesis 16:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Angẹli Olúwa sì rí Hagari ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ṣuri.
Genesis 16:7 in English
Genesis 16:7 · Berean Standard Bible
Now the angel * of the LORD found Hagar by a spring of water in the desert—the spring along the road to Shur.
Context
5Nígbà náà ni Sarai wí fún Abramu pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹ mí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí Olúwa kí ó ṣe ìdájọ́ láàrín tèmi tìrẹ.” 6Abramu dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Sarai fi ìyà jẹ Hagari, ó sì sálọ. 7Angẹli Olúwa sì rí Hagari ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ṣuri. 8Ó sì wí pé, “Hagari, ìránṣẹ́ Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?”
Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sálọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Sarai ni.” 9Angẹli Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.