Gẹnẹsisi 14:21
Genesis 14:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba Sodomu sì wí fún Abramu pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”
Genesis 14:21 in English
Genesis 14:21 · Berean Standard Bible
The king of Sodom said to Abram, “Give me the people, but take the goods for yourself.”
Context
19Ó sì súre fún Abramu, wí pé,
“Ìbùkún ni fún Abramu ti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo,
Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé. 20Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.”
Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo. 21Ọba Sodomu sì wí fún Abramu pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.” 22Ṣùgbọ́n Abramu dá ọba Sodomu lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè, 23pé, èmi kì yóò mú láti fọ́nrán òwú títí dé okùn bàtà, àti pé, èmi kí yóò mú ohun kan tí ṣe tìrẹ, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Abramu di ọlọ́rọ̀.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.