Gẹnẹsisi 14:18
Genesis 14:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Melkisedeki ọba Salẹmu* sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo.
Genesis 14:18 in English
Genesis 14:18 · Berean Standard Bible
Then Melchizedek king of Salem brought out bread and wine—since he was priest of God Most High *—
Context
16Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọti pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tókù. 17Nígbà tí Abramu ti ṣẹ́gun Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Sodomu lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (èyí ni àfonífojì Ọba). 18Melkisedeki ọba Salẹmu* sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo. 19Ó sì súre fún Abramu, wí pé,
“Ìbùkún ni fún Abramu ti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo,
Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé. 20Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.”
Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.