Gẹnẹsisi 13:6
Genesis 13:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀.
Genesis 13:6 in English
Genesis 13:6 · Berean Standard Bible
But the land was unable to support both of them while they stayed together, for they had so many possessions that they were unable to coexist.
Context
4Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa. 5Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́. 6Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. 7Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà. 8Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.