Galatia 6:13
Galatians 6:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí àwọn tí a kọ ní ilà pàápàá kò pa òfin mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ mú yin kọlà, kí wọn lè máa ṣògo nínú ara yín.
Galatians 6:13 in English
Galatians 6:13 · Berean Standard Bible
For the circumcised do not even keep the law themselves, yet they want you to be circumcised that they may boast in your flesh.
Context
11Ẹ wo bí mo ti fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé gàdàgbà-gàdàgbà sí yín. 12Iye àwọn tí ń fẹ́ ṣe àṣehàn ni ara wọn ń rọ yín láti kọlà; kìkì nítorí pé kí a má ba à ṣe inúnibíni sí wọn nítorí àgbélébùú Kristi. 13Nítorí àwọn tí a kọ ní ilà pàápàá kò pa òfin mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ mú yin kọlà, kí wọn lè máa ṣògo nínú ara yín. 14Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jesu Kristi Olúwa wa, nípasẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé. 15Nítorí pé nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà, bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.