Galatia 4:10
Galatians 4:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin ń kíyèsi ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún.
Galatians 4:10 in English
Galatians 4:10 · Berean Standard Bible
You are observing special days and months and seasons and years!
Context
8Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti ṣe ẹrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ìṣẹ̀dá. 9Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà tí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tan tàbí kí a sá kúkú wí pé ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, èéha ti rí tí ẹ tún fi yípadà sí aláìlera àti agbára ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá ṣe ẹrú? 10Ẹ̀yin ń kíyèsi ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún. 11Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín. 12Ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dàbí èmi: nítorí èmi dàbí ẹ̀yin: ẹ̀yin kò ṣe mí ní ibi kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.