Galatia 3:12
Galatians 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.”
Galatians 3:12 in English
Galatians 3:12 · Berean Standard Bible
The law, however, is not based on faith; on the contrary, “The man who does these things will live by them.”*
Context
10Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n”. 11Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.” 12Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” 13Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.” 14Ó gbà wá là ki ìbùkún Abrahamu ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kristi Jesu; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.