Galatia 2:3
Galatians 2:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà.
Galatians 2:3 in English
Galatians 2:3 · Berean Standard Bible
Yet not even Titus, who was with me, was compelled to be circumcised, even though he was a Greek.
Context
1Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jerusalẹmu pẹ̀lú Barnaba, mo sì mú Titu lọ pẹ̀lú mi. 2Mo gòkè lọ nípa ohun ti a fihàn mi, mo fi ìyìnrere náà tí mo ń wàásù láàrín àwọn aláìkọlà yé àwọn tí ó jẹ́ ẹni ńlá nínú wọn, èyí i nì ní ìkọ̀kọ̀, kí èmi kí ó má ba á sáré, tàbí kí ó máa ba à jẹ́ pé mo ti sáré lásán. 3Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà. 4Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè. 5Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìyìnrere náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.