Native Bible

Galatians 2:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì!

Galatians 2:17 in English

Galatians 2:17 · Berean Standard Bible

But if, while we seek to be justified in Christ, we ourselves are found to be sinners, does that make Christ a minister of sin? Certainly not!

Context

15“Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀, 16tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin, nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre. 17“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì! 18Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fi ara mi hàn bí arúfin. 19“Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láààyè sí Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.