Esra 9:2
Ezra 9:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da irú-ọmọ ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tókù yọ nínú híhu ìwà àìṣòótọ́.”
Ezra 9:2 in English
Ezra 9:2 · Berean Standard Bible
Indeed, the Israelites have taken some of their daughters as wives for themselves and their sons, so that the holy seed has been mixed with the people of the land. And the leaders and officials have taken the lead in this unfaithfulness!”
Context
1Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá, wọ́n sì wí pé, “Àwọn ènìyàn Israẹli, tí ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Jebusi, àwọn ará Ammoni, àwọn ará Moabu, àwọn ará Ejibiti àti ti àwọn ará Amori. 2Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da irú-ọmọ ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tókù yọ nínú híhu ìwà àìṣòótọ́.” 3Nígbà tí mo gbọ́ èyí, mo fa àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi ya, mo tu irun orí àti irùngbọ̀n mi, mo sì jókòó ní ìjayà. 4Nígbà náà ni gbogbo àwọn tí ó wárìrì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Israẹli kó ara wọn jọ yí mi ká nítorí àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn yìí. Èmi sì jókòó níbẹ̀ ní ìjayà títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.