Native Bible

Ezra 9:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá, wọ́n sì wí pé, “Àwọn ènìyàn Israẹli, tí ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Jebusi, àwọn ará Ammoni, àwọn ará Moabu, àwọn ará Ejibiti àti ti àwọn ará Amori.

Ezra 9:1 in English

Ezra 9:1 · Berean Standard Bible

After these things had been accomplished, the leaders approached me and said, “The people of Israel, including the priests and Levites, have not kept themselves separate from the surrounding peoples whose abominations are like those of the Canaanites, Hittites, Perizzites, Jebusites, Ammonites, Moabites, Egyptians, and Amorites.

Context

1Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá, wọ́n sì wí pé, “Àwọn ènìyàn Israẹli, tí ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Jebusi, àwọn ará Ammoni, àwọn ará Moabu, àwọn ará Ejibiti àti ti àwọn ará Amori. 2Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da irú-ọmọ ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tókù yọ nínú híhu ìwà àìṣòótọ́.” 3Nígbà tí mo gbọ́ èyí, mo fa àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi ya, mo tu irun orí àti irùngbọ̀n mi, mo sì jókòó ní ìjayà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.