Native Bible

Ezra 8:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì jíṣẹ́ àṣẹ ọba fún àwọn ìjòyè àti àwọn baálẹ̀ agbègbè Eufurate, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn àti ilé Ọlọ́run.

Ezra 8:36 in English

Ezra 8:36 · Berean Standard Bible

They also delivered the king’s edicts to the royal satraps * and governors of the region west of the Euphrates,* who proceeded to assist the people and the house of God.

Context

34Gbogbo nǹkan ni a kà, tí a sì wọ̀n, gbogbo iye ìwọ̀n ni a sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ní ìgbà náà. 35Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn tí ó ti padà láti ilẹ̀ àjèjì rú ẹbọ sísun sí Ọlọ́run Israẹli: akọ màlúù méjìlá fún gbogbo Israẹli, àgbò mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún, ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rin, àti òbúkọ méjìlá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo èyí jẹ́ ẹbọ sísun sí Olúwa. 36Wọ́n sì jíṣẹ́ àṣẹ ọba fún àwọn ìjòyè àti àwọn baálẹ̀ agbègbè Eufurate, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn àti ilé Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.