Native Bible

Ezra 7:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó jẹ́ kí ojúrere rẹ̀ tàn kàn mí níwájú ọba àti àwọn olùbádámọ̀ràn àti ní iwájú àwọn alágbára ìjòyè ọba. Nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára mi, mo mú ọkàn le, mo sì kó àwọn olórí jọ láàrín àwọn ènìyàn Israẹli láti gòkè lọ pẹ̀lú mi.

Ezra 7:28 in English

Ezra 7:28 · Berean Standard Bible

and who has shown me favor before the king, his counselors, and all his powerful officials. And because the hand of the LORD my God was upon me, I took courage and gathered the leaders of Israel to return with me.

Context

26Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ìgbọ́ràn sí òfin Ọlọ́run rẹ àti sí òfin ọba ní ó gbọdọ̀ kú tàbí kí a lé e jáde tàbí kí a gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù rẹ̀ tàbí kí a sọ ọ́ sínú ẹ̀wọ̀n. 27Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ẹni tí ó fi sí ọkàn ọba láti mú ọlá wá sí ilé Olúwa ní Jerusalẹmu ní ọ̀nà yìí. 28Ẹni tí ó jẹ́ kí ojúrere rẹ̀ tàn kàn mí níwájú ọba àti àwọn olùbádámọ̀ràn àti ní iwájú àwọn alágbára ìjòyè ọba. Nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára mi, mo mú ọkàn le, mo sì kó àwọn olórí jọ láàrín àwọn ènìyàn Israẹli láti gòkè lọ pẹ̀lú mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.