Esra 4:10
Ezra 4:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí ẹni ọlá àti ẹni ọ̀wọ̀ Asnappari kó jáde, tí ó sì tẹ̀ wọ́n dó sí ìlú Samaria àti níbòmíràn ní agbègbè e Eufurate.
Ezra 4:10 in English
Ezra 4:10 · Berean Standard Bible
and the rest of the peoples whom the great and honorable Ashurbanipal * deported and settled in the cities of Samaria and elsewhere west of the Euphrates.*
Context
8Rehumu balógun àti Ṣimṣai akọ̀wé jùmọ̀ kọ́ ìwé láti dojúkọ Jerusalẹmu sí Artasasta ọba báyìí: 9Rehumu balógun àti Ṣimṣai akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tókù—àwọn ará Dina, ti Afarsatki, ti Tarpeli, ti Afarsi, Ereki àti Babeli, àwọn ará Elamu ti Susa, 10pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí ẹni ọlá àti ẹni ọ̀wọ̀ Asnappari kó jáde, tí ó sì tẹ̀ wọ́n dó sí ìlú Samaria àti níbòmíràn ní agbègbè e Eufurate. 11(Èyí ni ẹ̀dà ìwé tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i.)
Sí ọba Artasasta,
láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin agbègbè Eufurate. 12Ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn ará Júù tí ó gòkè wá sọ́dọ̀ wa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti lọ sí Jerusalẹmu wọ́n sì ń tún ìlú búburú àti ìlú ọlọ̀tẹ̀ ẹ nì kọ́. Wọ́n ń tún àwọn ògiri náà kọ́, wọ́n sì ń tún àwọn ìpìlẹ̀ náà ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.