Native Bible

Ezra 2:69 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ́gbẹ̀rún (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) fàdákà àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀wù àlùfáà.

Ezra 2:69 in English

Ezra 2:69 · Berean Standard Bible

According to their ability, they gave to the treasury for this work 61,000 darics of gold,* 5,000 minas of silver,* and 100 priestly garments.

Context

67ràkunmí jẹ́ irinwó ó lé márùndínlógójì (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rin lé lọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6,720). 68Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀. 69Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ́gbẹ̀rún (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) fàdákà àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀wù àlùfáà. 70Àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Israẹli ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.