Esra 2:62
Ezra 2:62 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.
Ezra 2:62 in English
Ezra 2:62 · Berean Standard Bible
These men searched for their family records, but they could not find them and so were excluded from the priesthood as unclean.
Context
60Àwọn ọmọ
Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (652). 61Àti nínú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà.
Àwọn ọmọ:
Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi a sì ń fi orúkọ náà pè é). 62Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́. 63Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu. 64Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.