Esekiẹli 8:6
Ezekiel 8:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra ńlá tí ilé Israẹli ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù èyí lọ.”
Ezekiel 8:6 in English
Ezekiel 8:6 · Berean Standard Bible
“Son of man,” He said to me, “do you see what they are doing—the great abominations that the house of Israel is committing—to drive Me far from My sanctuary? Yet you will see even greater abominations.”
Context
4Sì kíyèsi i, ògo Ọlọ́run Israẹli wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìran ti mo rí ni pẹ̀tẹ́lẹ̀. 5Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu-ọ̀nà ibi pẹpẹ. 6Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra ńlá tí ilé Israẹli ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù èyí lọ.” 7Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. 8Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.