Esekiẹli 47:6
Ezekiel 47:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó bi mí léèrè pé, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?” Lẹ́yìn náà, ó mú mi padà sí etí odò.
Ezekiel 47:6 in English
Ezekiel 47:6 · Berean Standard Bible
“Son of man, do you see this?” he asked. Then he led me back to the bank of the river.
Context
4Ó sì wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba ibi odò tí ó jì ní ìwọ̀n orúnkún. Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba odò tí ó dé ìbàdí. 5Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsin yìí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jì tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni. 6Ó bi mí léèrè pé, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?”
Lẹ́yìn náà, ó mú mi padà sí etí odò. 7Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò. 8Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń tú jáde sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì wọ inú Òkun lọ, a sì mú omi wọn láradá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.